Komisanna fun oro awon Obinrin ati omokekeke nipinle Osun, Alhaja Latifat Abiodun Giwa ti so pe o wu Gomina Aregbesola lati se daadaa ni saa isejoba re akoko sugbon se ni opo awon komisanna igba yen maa n fi oogun senu ba a soro.
Nibi eto kan ti egbee Muslim Political Awareness Front (MUPAF) gbe kale nilu Osogbo lati la awon musulumi loye nipa eto idibo ni Giwa ti ni gbogbo nnkan to sele si gomina nigba naa kii se oju lasan.
Giwa ni ti awon komisanna igba yen ba ti fee gba nnkan lowo Aregbesola, se ni won maa n fi oogun senu ati pe awon miin tie gbe ere (statue) kale ti won pe eleda gomina si, ti won si maa n lo lati darii re bo se wu won.
Obinrin yii fi kun oro re pe looto ni Aregbesola gbiyanju ni saa akooko sugbon o fee se ju bee lo bi ki baa se ti awon komisanna ti won gbe opolo re sinuu igba.
"Enikan ti fee ri gomina ri nigba yen, bo se debe lo koko sa wonu ile igbonse, nigba to bo sita lawon eso alaabo gomina da a duro, won ye ara re wo, iyalenu lo si je pe oogun abenugongo ni won ba lapo re".
No comments:
Post a Comment