Ajo UNICEF pe fun isinmi osu mefa fawon iya to ba sese bimo

Lati le je kawon omotuntun ni anfaani si oyan daada fosu mefa akoko, ajo UNICEF ti so pe o ye kijoba pelu awon onileese adani maa fun awon iyalomo ni isinmi osu mefa gbako ni kete ti won ba bi omo.





Akosemose nipa ohun ti enu nje fun ajo naa, Ada Ezeogu lo soro yii nibi idanileko kan to waye pelu awon oniroyin lati wa ojutuu si bi o se nira fun opolopo awon omode lati lanfaani si ounje afaralokun lorileede yii.

Ezeogu ni amukun ti eru re wo lati isale loro naa, o ni ko si bi omo ti ko lanfaani si oyan daada losu mefa akooko se le lopolo pipe nigba to ba dagba .

O ni oyan lailabula pon dandan fawon omode losu mefa akooko ti won ba dele aye nitori opolopo anfaani lo wa ninu e ti iyalomo ba le farada igbese naa.

Akosemose naa ni looto ni opo nnkan bii airowo osu gba ati aisi alaanu maa n sokunfa bi opo obinrin kii fi lagbara lati fun awon omo loyan daada sugbon o ni oyan maa n dena oniruuru arun lara awon omode.

O wa ro awon iyalomo lati mu imototo nibaada ninu ohun gbogbo ti won ba n se, ki won si mo pe opolo omo to ba mu oyan daada maa n ji pipe nileewe ati nibiise .

No comments:

Post a Comment