Ojoojumo ni iye awon omo ti ko ri ounje to saraloore je n po si ni Naijiria - Adeneye


Komisanna foro iroyin nipinle Ogun, Otunba Adedayo Adeneye ti ke si gbogbo awon lookolooko lorileede yii lati tete wa nnkan se si bi iye awon omo ti ko lanfaani si awon ounje to ni eroja to n se araloore se n po sii lojoojumo.



Nibi eto itaniji kan tileese re pelu ajo UNICEF sagbekale re fawon oniroyin lo ti salaye pe Naijiria lorileede keji lagbaye ti awon omo ti won ko ri ounje to saraloore je po ju si.

Nibi eto to da lorii bi awon omode se n jeun si ohun ni Adeneye ti so pe kii se asiko niyi funjoba atawon ti oro kan lati kawogbera, paapa nigba to je pe awon omo ti ko lagbara loro naa kan.

O ni ijoba ipinle Ogun ti ko ipa tire nipase ipese itoju to peye fawon alaboyun atawon omo kekeke. O ni lara eto naa ni eto adojutofo ti won pe ni Araya ati Gbomoro.

Komisanna yii waa ro awon oniroyin lati ke gbajare lori oro airi ounje onilera je laarin awon omokekeke lorileede yii titi ti awon ti oro kan yoo fi gbe igbese to to lorii re.

No comments:

Post a Comment