Ọṣun 2018: Idi ti Peter Babalọla fi tayọ awọn oludije to ku


Awon asaaju ẹgbẹ oselu APC nipinle Osun ti wa nikorita ẹlẹgẹ ni bayii ti idije ti bere lati mo eni ti yoo gbapo lọwọ Gomina Rauf Aregbesola, eni ti ọkọ isejoba re ti n lọ sebute diedie.

Eleyii ko seyin ọkẹ aimọye awon ti won nife lati gbapo naa lowo Aregbesola pelu awon  ti won tun si n ba awon lookolooko kaakiri ipinle Osun sepade lori erongba won lati dije.

Atunwi asan ni taa ba so pe Gomina Aregbesola ti fi iyun lelẹ lori ona teeyan maa n gba sejoba nipinle Osun. Koda, awon alatako isejoba yii gan an ko le foju fo awon ise akanse to je ojulowo, to si ti mu ayipada nla ba awon araalu tijoba yii se l'Osun. 

Bere lati atunse oju-ona Osogbo si Ila Odo titi de aala ipinle Kwara, to fi mo biriiji awoyanu ti won pe ni Bisi Akande Trumpet  Bridge to wa lorita Gbongan pelu oju-ona Oba Adesoji Aderemi East By Pass, Aregbesola ti sopinle Osun di apewaawo ninu awon ise idagbasoke oniruuru.

Awon igbese ribiribi tijoba Aregbesola gbe wonyii ti waa ru ireti awon eniyan soke pe ipinle Osun, eyi to ti figba kan wa nipo eyin, naa le di ilu nla ti olaju wa lorileede yii.

Latari idi eyi, o waa pon dandan lati wa eni to ni iriri ninu isejoba to si yẹ ninu ohun gbogbo lati gba eeku ida isakoso lowoo Gomina Aregbesola.

Osun nilo olopolo pipe, olooto ati eni to tẹpa mọṣẹ, eni to lafojusun pelu irele ninu ohun gbogbo, eni ti yoo mu awon koko isejoba elega mẹfa Ogbeni Rauf Aregbesola lokunkundun.

Ni temi o, mo n la ala pe  eni ti yoo gbajoba lowo Aregbesola gbodo je ologbon lati maa fi oye ati imo oselu yanju ipenija to le dide ninu oselu. O si gbodo ni arojinle nipa ona ti aa gba mu nnkan derun sii fawon araalu. 

Bo tile je pe ko tii so gbangba pe oun nife lati dije, o dabi eni pe gbogbo oju wa lara Dokita Peter Adebayo Babalola, eni to ti ni iriri nla ninu oselu fun bii ogun odun laarin nnkan odun metadinlogbon ti won ti da ipinle Osun sile.

Omobibi ilu Ikire tii se okan lara awon ilu meta ti ibo po ju si niha ekun Iwo-Oorun nipinle Osun, Adebayo ni awon nnkan amuye to to lati deruba oludije yoowu to ba tun fee jade.

Komisanna to lapa rere nileese eto ogbin ati ohun alumooni ni Babalola ko too se olori awon osise loofiisi gomina. Lowolowo bayii, oun ni alaga ajo to n mojuto oro awon ijoba ibile nipinle Osun.

Lakooko, awon alakale tijoba to wa lode bayii n sise tọ ko se ajeji si Babalola, akinkanju ni ninuu isakoso awon eniyan, paapa awon oloselu l'Osun nijoba ibile.

Yato si eleyii, oro oselu Osun fun Babalola lanfaani nla lati gba eeku-ida isakoso lowoo Aregbesola. Nipase awon ipo to ti di mu, o ti ni opolopo anfaani lati ba oniruuru awon eeyan pade kaakiri korokondu nipinle Osun, eleyii si so o di aayo gbogbo awon ti won ti salabapade re lona kan tabi omiin bi idije se n lo.
 
Bere lati odo awon ori-ade, lo sodo awon elegbejegbe, egbe awon osise, egbe awon oniruuru esin, osise ijoba, awon onise-owo, to fi mo awon oniroyin, Babalola je enikan to konimora, eni to see fokantan ati eni to foribale labe isakoso ati idari egbe oselu to wa, gbogbo awon nnkan wonyii lawon eeyan mo kaakiri woodu bii oodunrun to wa nipinle Osun, yoo si so eso rere ti egbe oselu APC ba le gbe Peter sile gege bii oludije won.

Isejoba lode oni nilo ibasepo to dan monran pelu awon ara oke-okun atawon onileese aladani, gbogbo amuye yii si ni Peter ni nitori opo odun seyin lo ti n gba awon eeyan sise kaakiri origun mereerin orileede yii gege bii oludari ati alase Pebaylat Oil and Gas Limited.

Mimu eleyii wa si iṣe ninu isejoba l'Osun pelu ogbon inu ti Eleda fi jinki Babalola, a je pe itesiwaju nla ni yoo tubo sele ti Gomina Aregbesola ba ti lo.

Eleyii to gbeyin re ni itaniji ati ariwo to n lo kaakiri diedie nipinle Osun bayii pe ẹkun Iwo-oorun ni gomina kan ninu idibo to n bo lona ohun. Ti awon adari egbe ba le ri isepataki eleyii, a je pe ohun gbogbo yoo sise po si rere fun Babalola niyen.

Eni to mojuleja ipinle Osun ni Babalola, ibe lo ti lo sileewe alakobere ati girama ko too koja si The College of International Marine, Colombo, Sri-Lanka, leyin igba yen lo lọ si Liverpool Polytechnic, UK. O keko gboye ninu imo Transport Planning ni Lagos State University.

Alagba ni Dokita Peter Adebayo Babalola ninu ogba ajara Olorun, eni ti a ti gbe yewo to si kun oju osunwon ni,  oloselu to see mu yangan ni nileloko kaakiri ilu Ikire ati nipinle Osun.


Busayo ko iwe yii latilu Iree, nijoba ibile Boripe nipinle Osun.

No comments:

Post a Comment