APC nilo Dokita Okowa fundibo abele to kunju osunwon - Fayose

Gomina ipinle Ekiti, Ayodele Fayose ti so pe egbe oselu APC nilo eniyan bii Dokita Ifeanyi Okowa tipinle Delta fun idibo abele to gbounje fegbe to tun gba awo bo.




Ninu oro idupe re leyin ti Dokita Ifeanyi Okowa kede Ojogbon Kolapo Olusola Eleka gege bi eni to jawe olubori nibi idibo abele egbe oselu PDP to waye nipinle Ekiti ni Fayose ti ni eko nla ati awokose ni idibo naa je fegbe APC.

Fayose ni nnkan itiju ni bi egbe APC se pari idibo tiwon lojoo satide to koja pelu ada ati ija nla, o ni Gomina Okowa to waa sedibo ohun fun PDP je olopolo pipe eda.

Kidibo abele naa to bere ni Seneto Olujinmi ti so pe oun ko kopa mo, to si seleri atileyin fun Omooba Dayo Adeyeye, eleyii lo so awon oludije di meji pere.

Leyin idibo naa, Olusola Eleka ni ibo egbefa o din mesan (1,191) nigba ti Adeyeye ni ibo ojidinlegberin ati mewa.

Gomina Okowa waa kede Ojogbon Olusola gege bii oludije to jawe olubori ninu idibo naa, oun ni yoo si koju awon oludije latinu egbe oselu to ku ninu idibo gomina ti yoo waye losu keje odun yii.

No comments:

Post a Comment