Gbogbo awon alaga kansu atijoba ibile agbegbe ti won sese yan l'Osun bayii ni inu won ko dun lowolowo yii latari jibiti nla ti won nigbagbo pe o lu won.
Ni kete ti awon kanselo ti won dibo yan yan alaga kookan lawon ijoba ibile metadinlaadorin to wa l'Osun la gbo pe Gomina Aregbesola pase pe won gbodo lo fun idanileko kan loke-okun.
Asiko yii ni okunrin kan, Albert Adeyemi tawon eeyan gbagbo pe o sunmo Gomina Aregbesola, to si tun je kongila l'Osun yoju pe oun yoo ba won seto irinna idanileko ohun.
Egberun lona oodunrun naira la gbo pe akapo egbe oselu APC l'Osun gba lowo okookan awon alaga naa, eleyii ti apapo owo ohun si je milioonu lona ogun naira o le egberun kan N20.1m.
Tayotayo la gbo pe awon alaga ohun fi gbera l'Osun laipe yii, ti won si ti dagbere ilu oyinbo fawon araale won, sugbon jebete gbe omo le won lowo nigba ti won de papako ofurufu ti awon oyinbo ko fun won niwe-irinna.
Pelu ibinu ni won fi pada wa sile, sugbon latigba naa ni won ko ti ri eegun to n je Adeyemi, se lo n yi won soke-sodo, ko da owo pada fun won, bee ni akapo egbe ti won dawo si lowo ko so nnkan kan lori isele naa.
Nigba tawon oniroyin pe Adeyemi lati gbo tenu, se lo ni oun ko le so ohunkohun laikoko mo ibi ti asiri naa ti lu sita ati pe kawon oniroyin loo ko nnkan ti won ba fe tori oun ko ba won lejọ.
No comments:
Post a Comment