Komisanna feto idajo nipinle Osun, Dokita Ajibola Basiru ti so pe kikuro ti Alhaji Fatai Diekola kuro ninu egbe oselu APC ko lee tu iru kankan lara aseyori egbe naa ninu idibo to n bo.
Nibi eto kan ti egbe APC Osun se lati fi gba ese awon omo egbe oselu PDP danu leyin ipade apapo egbe naa to waye nilu Osogbo lopin ose to koja ni Ajibola ti ni ibi ti Diekola ba ti n jeun nikan lo mo.
O ni agbasese oloselu ni Diekola, kontiraati lo maa n le kaakiri inu egbe oselu to ba lo, to ba si ti rii pe ise ti tan, kia lo tun maa ta kosọ sinu egbe oselu miin.
Ajibola fi kun oro re pe bi Diekola se kuro ko lee mi egbe oselu APC rara, bee ni ko le nipa kankan lori idibo gomina ti yoo waye losu kesan odun yii nitori gbogbo ilu lo feran Gomina Aregbesola latari awon ise meremere to ti se l'Osun.
A oo ranti pe laipe yii ni Alhaji Diekola, eni to je omobibi ilu Osogbo kuro ninu egbe oselu APC bo sinu egbe PDP pelu alaye pe isejoba ti ko laanu ni Aregbesols n se l'Osun.
No comments:
Post a Comment