EID-EL FITRI: Babayẹmi rọ awọn musulumi lati mase gbagbe ẹkọ Ramadan


Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ti rọ awon musulumi lati mase ya kuro ninu eko ifaraẹnijin ati ti ife tooto ti osu aawe Ramadan kọ wọn.

Lasiko ti Babayemi n ki won ku oriire oju won to ri ayeye odun itunu aawe lo ti salaye pe asiko aawe Ramadan kun fun eko nipa didari-jin enikeni to ba ṣẹ wa ati ninawọ ifẹ si awọn to ba ku die kaato fun lawujọ.

Oludije funpo ile igbimo asofin agba lati ẹkun Iwo-oorun Osun lasiko idibo to koja sọ siwaju pe gbogbo igba ni awọn musulumi gbodo maa ranti iwa ati iṣe won lasiko Ramadan, ki won si maa mu u lo ki aye le rọrun fun gbogbo ẹlẹsinjẹsin.

Omooba Babayemi wa ro awon musulumi atawon ti kii se musulumi kaakiri ipinle Osun ati orileede yii latinlo asiko ayeye odun itunu aawe yii fun adura pataki fun awon adari lorileede Naijiria.

O salaye pe bi gbogbo nnkan tile n kọnilominu lọwọlọwọ bayii, paapaa lori oro eto-aabo ati ọrọ-aje, sibe, a ko gbodo sọreti nu nitori laipe, iyanu a sẹlẹ.

Gege bo se wi, "Gbigbogun ti iwa jegudujera, magomago ninu idanwo, ija esin, gbigbogun ti iwa gbigbe sunmọmi, isejoba ti ko ri bo se yen ko ri ati bee bee lo, je eyi ti tolori-telemu gbodo fowosowopo lati se.

Babayemi tun wa rọ awon musulumi lati tun irinajo aye won se gẹgẹ bi Ramadan se kọ won, ki won si maa te siwaju lati waasu ife, alaafia, isokan ati itesiwaju.
@@@@@@@@

No comments:

Post a Comment