Ramadan 2019: Babayemi rọ awọn musulumi lati sunmọ Olorun sii


Omooba Dotun Babayemi ti rọ gbogbo awon musulumi lati sun mọ Olorun sii, ki won si tubo wa oju re fun idariji ese lasiko aawe Ramadan yii.

Babayemi, eni to dije funpo ile igbimo asofin agba orileede yii lati ekun Iwo-oorun Osun ninu idibo to koja sọ pe pataki aawe yii ni lati ya ara won soto, ki won si maa gbe igbe aye ododo.

O ni asiko aawe Ramadan wa lati kọ awon musulumi ni iwa irele ati lati ya kuro ninu gbogbo iwa aisedeede, kii se ki won kan maa fi ebi pa ara won lasan.

Omooba Babayemi rọ won lati tubo tẹra mọ aanu sise, paapaa, fun awon to ku die kaa to fun lawujo nitori okan pataki lara opo ti aawe gbigba duro le lori niyen.

Omobibi ilu Gbonga yii waa gbadura fun okun ati agbara fun awon obinrin lasiko aawe yii latari ipa takuntakun ti won maa n ko.

Bakan naa lo gba awon elesinjesin lorileede yii niyanju lati maa gbe ninu isokan ati ife, ki itesiwaju le wa kaakiri Naijiria.

No comments:

Post a Comment