Omooba Dotun Babayemi ti rọ gbogbo awon agbanisise lorileede yii lati maa bu iyi kun ise awon osise ti won n gba sise, ki ori won baa le ya lati maa se daadaa siwaju lenu ise.
Ninu ọrọ iwuri ti Babayẹmi fi ranse sawon osise gege bi won se n sayeye ojo won (workers' day) loni, o ni yiya ọjọ oni sọto lagbaye ko ṣeyin ọna lati je kawon osise mo pe ipa takuntakun ti won n ko nipa idagbasoke laarin awujo ko se e fi ọwọ rọ sẹyin.
Oloselu to dupo ile igbimo asofin agba orileede yii lati iha Iwo-oorun Osun ki awon osise, paapaa nipinle Osun, o ni o ti han gbangba pe imura sisẹ awon osise ni ọpakutẹlẹ ti idagbasoke ijoba tiwantiwa ati itesiwaju aṣa duro le lori kaakiri agbaye.
O ni bi awon agbanisise, yala ijoba tabi awon ileese aladani, ba se fowo to dara mu awon osise won naa ni awon osise gbodo mọ pe awon gbodo fi tokantokan pelu otitọ inu sise.
Babayemi ni ẹni to se e fokantan ati akikanju ni awon osise ijoba nipinle Osun, o si tun rọ won lati mase boju weyin rara ninu ipinnu won lati mu kipinle Osun ati orileede yii goke agba.
No comments:
Post a Comment