Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti n wa ọmọkunrin kan, Deji Adenuga lori esun pe o dana sun awon molebi orebinrin re, Tutu Sanumi nitori pe iyen so fun un pe oun o se mo.
Deji, eni ti a gbo pe o ti sewon ri ni wahala be sile laarin oun ati Titi, eni ti won ti jo n ba ere aniyan bo lati odun merin seyin, koda, oro naa le debii wi pe won ko ara won lo si agoo olopa, sugbon pabo lo ja si.
Bi Titi se so fun Deji pe o to gee bayii la gbo pe o ti kuro niluu Ondo laijẹ ki Deji mo. Pelu ibinu ni Deji fi lo sile awon Titi to wa loju-ona Igbokoda lojo Tusde, o gbe keegi epo petiroolu lọwọ, o si dogbon si windo ile naa laarin oru.
O da petiroolu sinu ile, o si ju isana si i, loju ese ni meji ninu awon molebi Titi ku, nigba tawon meje to ku dakẹ nileewosan Trauma Center niluu Ondo.
No comments:
Post a Comment