Fọfọ ni Orita-Ọlaiya niluu Osogbo kun bayii fun awon olokada ti won n fehonu han lori owo ti wọn sọ pe ijoba ipinle Osun n gba lọwọ wọn.
Awon olokada yii ni won so pe pelu bi eto oro-aje se le nipinle Osun bayii, ti awon si n tiraka lati wa ounje oojọ fawon molebi awon, se nijoba tun n di kun wahala tawon n koju.
Won ni ijoba gbe tikeeti kan jade, won si n gba igba naira (#200) lojoojumo lowo awon, bee lawon alakoso egbe olokada naa tun n gba aadota naira (#50) lowo awon.
Ibinu yii lo mu won fon sojuu titi, ti won si n pariwo pe awon ko le sanwo naa mọ. Won ni se ni kijoba wa ona ti nnkan yoo fi pada sipo nipinle Osun, ti igbe aye irorun yoo si ba gbogbo ilu.
No comments:
Post a Comment