Lobatan! Okuta ni won fi sin Oshiomole kuro nipinle Ogun


Ọtọ ni nnkan ti alaga egbe oselu APC lorileede yii, Adams Oshiomole ba nipinle Ogun lasiko ipolongo ibo saa eleekeji fun Aare Buhari ti won se nibe loni.

Gbogbo nnkan ti n lo deede nibere, afigba ti Oshiomole kede Dapo Abiodun gege bii oludije funpo gomina nipinle Ogun.

Bayii ni ariwo gba ori papa isere ti eto naa ti n waye kan, bi won se n ju okuta lu ọgangan ibi tawon lookolooko egbe APC joko si, ni won n pariwo ole le won lori.

Koda, won ko je ki Aare Buhari ri oro kankan so lasiko to bo siwaju lati soro, se ni won n pariwo pe Oshiomole lo da wahala sile fegbe APC nipinle Ogun.




Ohun ti a gbo ni pe awon alatileyin Gomina Ibikinle Amosun ni won n fehonu han, ko si si eni to le so ibi ti oro naa yoo yori si lasiko idibo gbogbogbo to n bo niwaju.

2 comments:

  1. I will like to get the email address of the publisher of this blog. Kindly send it to my email box. Thanks

    ReplyDelete