Alaga ajo eleto idibo orileede yii, Ojogbon Yakubu Mahmood ti so pe ko tii si imurasile to duro daadaa lati ọdọ ajọ naa fun eto idibo to ye ko waye loni, ojo kerindinlogun osu keji.
Yakubu ni oun ti sagbeyewo gbogbo imurasile ajọ INEC, oun si ri pe bi eto idibo alakoyawo yoo ba wa ninu eto idibo aare, awon omo ile igbimo asofin agba ati tawon omolee igbimo asofin apapo, o di dandan kawon sun idibo naa siwaju.
Nitori idi eyi, won sun idibo ti oni si ojo ketalelogun osu keji, nigba ti won sun ti gomina atawon omo ile igbimo asofin ipinle siwaju di ojo kesan osu keta.
No comments:
Post a Comment