Gbogbo eni to ba nifẹ idagbasoke orileede yii gbodo dibo fun Aare Buhari - Lasun Yusuff



Igbakeji abenugan ile igbimo asofin apapo orileede yii, Onorebu Lasun Yusuff ti so pe ona kansoso ti itesiwaju fi le ba awon ise idagbasoke to n lo lowo lorileede yii ni ki awon araalu dibo yan Aare Mohammadu Buhari gege bii aare leekeji.

Nibi eto ironilagbara kan ti Lasun se fun awon ọdọ atawon obinrin nijoba ibile Orolu/Irẹpodun/Osogbo/Olorunda lo ti ni ki awon omo orileede yii ronu oruko rere ti Buhari ti mu ba Naijiria yato si awon iwa buburu ti won mọ wa mọ tẹlẹ.

O ni Aare Buhari ti tun oruko orileede yii se kaakiri agbaye nitori pe oun funraare je olotito ati alakoyawọ adari, idi si niyii to fi tọ si saa keji gege bo se ri fun awon asaaju ti won ti dari nipo aarẹ kọja lorileede yii.

Nibi eto naa ni Lasun Yusuff ti fun okookan awon eeyan ti won je egberun kan ati aadorin (1070) ni egberun lona ogun naira, apapo owo to lo ọhun si le ni milioonu lona mokanlelogun naira.

Nipa idi to fi gbe eto naa kale, asofin yii ni oun mo itumo pe ki eeyan je alaini, idi si niyen toun fi maa n sa gbogbo ipa oun niwonba bo se mọ lati derin pẹẹkẹ awọn eeyan ti won ran oun nile igbimo asofin. 

O fi kun oro re pe ona kansoso toun fi le la ipa rere laarin awon eeyan oun ni ki oun san ona  idanileko fun won, ki oun si fun won niwonba owo ti won yoo fi bere ise naa pelu afojusun lati mu iṣẹ ati oṣi kuro lorileede yii.

Lasun wa seleri pe oun ko ni dawọduro lori awon nnkan ti oun n se fawon eeyan agbegbe ẹkun idibo ijoba apapo oun, ati pe loorekoore loun yoo maa gbe awon igbesẹ ti yoo maa mu aye rọrun fun won.




No comments:

Post a Comment