Asofin to n ṣoju awon eeyan Oriade/Obokun nile igbimọ asofin apapo orileede yii, Onorebu Oluwọle Ọkẹ ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri pe awọn alatilẹyin oun da wahala silẹ lagbegbe yẹn laipẹ yii.
Ọkẹ, eni to n soro lori esun kan ti oludije labẹ egbe oselu APC lagbegbe naa, Dokita Siji Olamiju fi kan an laipe yii pe o ko awon nnkan ija oloro wọ agbegbe ọhun pelu ifowosowopo DPO olopa nibe.
Onorebu yii ni gege bii amofin ati asofin, oun mo ewu to wa ninu kiko ibon kaakiri laigba ase lodo awon olopaa, oun ko si ni ase (licence) naa lowo rara lati ṣeru ẹ.
O ni aburo oun ni Olamiju, oun ko si si nipinle Osun lasiko ti wahala ti won n so ọhun sele, o ni awon omo egbe APC ti won je alatileyin Olamiju ni won da wahala naa sile leyin ti dokita naa fun won ni owo ti ko tẹ won lorun nigba to sabewo sodo wọn.
Ọkẹ fi kun oro re pe oun ko mo DPO ti won n so yen ri rara nitori ko si idi kankan toun fi le maa se wolewode pelu e. O ni aiti mọ oselu se daada lo fa wahala fun Olamiju.
O ni odu ni oun ninu oselu agbegbe Oriade/Obokun, kii se aimọ fun oloko, awon nnkan meremere toun ti se fawon araalu lo fa a ti awon alatileyin oun ninu egbe oselu APC gan an fi po ju ti inu egbe PDP gan an lo.
Gbogbo nnkan yii ti Olamiju ri lo sọ pe o fa a to fi n wa gbogbo ona lati fa oun sinu wahala, eleyii ti oun ko si le faaye rẹ sile lailai nitori aburo lo je fun oun ni gbogbo ona.
O wa ro awon alatileyin re lati mase faaye gba enikeni lati bi won ninu, saaju, lasiko ati leyin idibo ojo kerindinlogun osu keji odun yii, bee lo ro awon omo egbe APC lati dekun iwa ipa nitori idibo.
No comments:
Post a Comment