Egbe oselu PDP nipinle Osun ti ke si oga agba olopaa lorileede yii, Mohammed Adamu lati tete gbe igbese lori wahala ti Onorebu Adejare Bello ati Ajibola Basiru n gbero lati da sile.
Adejare Bello, eni to je abenugan ile igbimo asofin ipinle Osun nigba kan ri, oun si ni oludije funpo ile igbimo asofin apapo orileede yii bayii fun agbegbe Ede latinu egbe oselu APC, nigba ti Ajibola n dije lati di seneto fun ekun aaringbungbun Osun labe egbe APC kan naa.
Ninu atejade kan ti alaga egbe PDP, Onorebu Soji Adagunodo ati akowe egbe, Bola Ajao fi sita ni won ti ni asiri ipade ikọkọ kan ti Adejare ati Ajibola se laipe yii ti tu sawon lowo.
Ninu ipade naa ni won ti ni won fenuko lati lo awon tọọgi lati kọlu moto ipolongo Adagunodo ati ti Dokita Deji Adeleke to je okan lara awon asaaju ninu egbe PDP l'Ọṣun.
Atejade naa fi kun un pe won ti dẹ awon toogi sile lati ya bo awon egbe PDP nigba ti won ba lo sepolongo ibo, paapaa lagbegbe Ifelodun ati Osogbo.
Won wa ro ọga agba olopa lati mase fi oro naa sere rara, ki won bere iwadi kikun lori e, ki won ma si se faaye gba awon omo egbe oselu APC lati da wahala sile nipinle Osun saaju, lasiko ati leyin idibo to n bo yii.
No comments:
Post a Comment