Awon omo egbe oselu Accord nipinle Osun ti so pe leyin ti awon sagbeyewo gbogbo awon oludije funpo seneto niha Iwo-oorun Osun, gedegbe ni Omooba Dotun Babayemi ti egbe oselu ADP da yatọ.
Alaga egbe naa l'Osun, Alhaji Abdulganiyu Opawuyi lo salaye oro yii lasiko to ko ogunlogo awon omo egbe oselu Accord Party lo sodo Babayemi lati lo jẹjẹ atileyin won fun oludije naa.
Opawuyi, eni ti asaaju egbe Accord niha Iwo-oorun Osun, Alhaji Raheem Ayoola Fatai ba koworin lo sibe pelu awon omo egbe lo salaye pe leyin iwadi ati ayewo finnifinni nipa awon ti won jade funpo seneto lagbegbe naa lawon ri i pe Babayemi nikan lawon araalu nife si.
O seleri pe, o kere tan, ibo egberun lona ogun ati meji to je ti awon omo egbe oselu Accord niha Iwo-oorun Osun lawon yoo ko fun Babayemi lasiko ibo ojo kerindinlogun osu keji odun yii.
Opawuyi salaye pe igbese fifontẹ lu Babayemi naa wa lati le tete jẹ ko mọ pe gboingboin lawon wa leyin ẹ titi ti yoo fi saseyori, o ni gbogbo awon alaga egbe Accord lawon ijoba ibile kaakiri nipinle Osun lawon jo fikunlukun ko to di pe awon sabewo sodo oludije naa.
Gbogbo awon agbaagba egbe Accord ti won tele alaga won lo sibe ni won jeri pe ko si oloselu kankan lagbegbe naa to ti lapa rere ninu aye awon araalu bii Dokita Babayemi, idi si niyii ti gbogbo won fi pinnu lati ti oludije latinu egbe ADP ọhun leyin.
Ninu oro idupe re, Omooba Dotun Babayemi so pe inu oun ati gbogbo awon omo egbe oselu ADP dun fun abewo awon asaaju egbe Accord naa.
Babayemi seleri pe oun ko ni ja awon eeyan naa kulẹ rara ti won ba le fi ibo won gbe oun de ile igbimo asofin agba orileede yii losu to n bo.
No comments:
Post a Comment