2019: Awọn oludibo n'Iwọ-Oorun Ọsun seleri atileyin fun Dokita Babayemi



Ni bayii ti idibo gbogbogbo lorileede yii ti ku si dẹdẹ, awọn oludibo kaakiri woodu aadofa to wa niha ẹkun idibo Iwo-oorun ipinle Osun ti seleri atileyin won fun oludije funpo seneto lagbegbe naa, Omooba Dotun Babayemi, eni to n dije latinu egbe oselu Action Democratic Party (ADP).

Opolopo awon lookọlookọ ati oniruuru ẹgbẹ oselu lagbegbe naa ni wọn sọ pe gboingboin lawon wa leyin Babayẹmi, ati pe lasuko idibo ojo kerindinlogun osu keji odun yii lawon yoo safihan imuse awon ileri atileyin yii.
 
Lasiko ti Omooba Babayemi n sabewo odun kaakiri awon woodu naa lati ba won sajoyo odun keresi ati odun tuntun, pelu ebun ounje lorisiirisii to fun won, lawon eeyan fi tifetife gba oludije ohun, won si so fun un pe ko fokanbale nitori pe lodo re ni ibo awon wa.

Latijoba ibile Iwo, OlaOluwa ati Ayedire ni Babayemi ti bere abewo naa, ninu eyi ti oun pelu awon asaaju egbe ADP ti jo koworin, won si lo akooko naa lati ran awon eeyan leti erongba re lati soju won nile igbimo asofin agba orileede yii fun erejẹ ijoba tiwantiwa to muna doko.

Ninu oro re, Alhaji Moshood Adeoti, eni to je oludije funpo gomina ninu idibo odun to koja latinu egbe oselu naa ro awon araalu lati satileyin fun Babayemi gege bi won se se foun lasiko idibo to koja.

Adeoti salaye pe olotito ati oloselu to se e fokantan ni Babayemi, yoo si je asoju rere fawon eeyan agbegbe Iwo-Oorun Osun ti won ba le fi ibo won gbe e wole losu keji odun yii.

Bakan naa ni ogunlogo awon omo egbe oselu SDP lagbegbe ohun lo asiko naa lati darapo mo egbe oselu ADP latari awon nnkan meremere ti won ni Dokita Babayemi n gbe se lati ori eto eko, de ori eto iwosan ati oniruuru iranlowo fun awon obinrin laika ti egbe oselu ti won wa si.

Awon omo egbe oselu African Democratic Congress, ADC ni Ogbaagba nijoba ibile OlaOluwa naa seleri lati dibo won fun Babayemi, eni ti won sapejuwe bii adari to yatọ, ti ko si nii gbagbe awon araalu to ba de ile igbimo asofin agba.

Bakan naa loro ri fun Omooba Babayemi nijoba ibile Ejigbo, Egbedore, Ariwa Ede, Gusu Ede, Ayedaade, Irewole ati Isokan, gbogbo awon araalu ni won so pe enikan soso tawon nigbekele ninu e laarin awon oludije funpo senetọ lati agbegbe naa ni Babayemi, o si ti to asiko fun un lati jere ise rere owo ẹ.

Babayemi dupe lowo awon eeyan woodu aadofa ohun, o si rọ won lati mase ta ojo ola won ati tawon omo won nitori ohunkohun, ki won fi ooto inu duro ti oun lasiko idibo osu keji ọhun.

No comments:

Post a Comment