Ope o! Gomina Oyetola pese oko-ojuurin ofe fun irin-ajo odun keresimesi ati odun tuntun


Lati le mu ki irinajo odun keresimesi ati odun tuntun rorun fun awon eeyan ipinle Osun ti won n gbe nilu Eko ati agbegbe re, gomina ipinle Osun, Alhaji Gboyega Oyetola ti kede pe ipese oko ojuurin ofe ti wa nile fun won.


Gege bi atejade kan to jade lati ileese okoowo ati alajeseku nipinle Osun se fidi ẹ mulẹ, oko ojuurin, eleyii ti won pe ni "Omoluabi Train" yoo gbe awon eeyan naa wa latipinle Eko saaju ojo odun, bee ni yoo tun da won pada leyin odun laigba owo kankan lowoo won.

Gege bo se wi, Satide, ojo kejilelogun osu kejila odun yii ni oko ojuurin naa yoo gbera  ni Iddo Terminus nipinle Eko laago mewa aaro fun ayeye odun keresimesi.

Bakan naa ni yoo gbera nibe lojọ kokandinlogbon osu kejila odun yii wa sipinle Osun, ti yoo si gbe won pada silu Eko lojo keji osu kinni odun 2019.

Atejade ohun fi kun un pe anfaani wa fun awon omo ipinle to yi ipinle Osun ka ti won n gbe nipinle Eko, Ogun, Ekiti ati Oyo lati samulo oko ojuurin ofe naa.

Eto yii, gege bo se wi, wa lati le je ki won lanfaani lati waa ba awon ololufe atawon araale won se odun pelu inu didun laisi ironu owo ọkọ nibẹ.

A oo ranti pe lati odun 2010 nijoba Ogbeni Aregbesola ti bere ipese oko-ojuurin ofe lawon asiko odun, idunnu lo si je fun awon eeyan lati gbo pe ijoba tuntun yii n te siwaju ninu eto naa.

No comments:

Post a Comment