Ope o! Funke Jenifa di Iya Ibeji

Okan pataki lara awon osere tiata obinrin lorileede yii, Funke Akindele ti gbogbo eeyan mo si Jenifa la gbo pe o ti bimo bayii.


Jenifa lo koko bo sori ero istagramu re nibi to ti so pe "Olorun tobi, a ti fi oruko tuntun pe mi".

Bayii ni awon osere tiata lede Yoruba ati ede Oyinbo n so kaakiri lori ero ayelujara pe Olorun ti fi ibeji lantilanti jinki idile Jenifa ati JJC Skillz ọkọ rẹ

A oo ranti pe awon wolii kan ti so lodun die seyin pe Jenifa le ma bimo fun JJC Skillz, sugbon ni bayii ti oro naa ko wa si imuse, gbogbo aye lo n ba Jenifa dupe lowo Olorun.

No comments:

Post a Comment