Famurewa rọ awon araalu lati samulo ifẹ ti keresimesi duro le

Onorebu Ajibola Isreal Famurewa to n soju awon eeyan agbegbe ekun idibo ijoba apapo ti Gusu Ijesa nile igbimo asofin apapo orileede yii ti ro awon kristiani lati samulo ẹkọ ifẹ ti odun keresimesi duro le lori ninuu gbogbo idawole won.

Famurewa ro won lati maa polongo ife, alaafia ati isokan ninu iwa ati ise won nipinle Osun ati lorileede Naijiria laapo.

Ninu oro ikini ku odun keresimesi re, Famurewa, eni to n dije dupo Seneto lagbegbe Ife/Ijesa labe egbe oselu APC bayii salaye pe ara-ọtọ ni odun keresi eleyii je lorileede Naijiria pelu oniruuru itesiwaju ti Aare Mohammadu ti mu ba ekajeka.

O ni gbogbo awon arinrinajo ojuupopo nlanla lorileede yii ni won mo pe irorun ni irinajo won kaakiri fun odun keresimesi ba de pelu awon oju ona to dara.

Yato si eleyii, Famurewa ni ko si ato-fi-mu-le-mu lawon ileepo lasiko odun yii gege bo se maa n wa tele, eleyii to tumo si pe iyato ati ayipada rere ti n ba wa lorileede Naijiria.

O wa ro gbogbo awon araalu lati fi ife yii dibo fun gbogbo awon oludije labe asia egbe oselu APC kaakiri orileede yii ninu idibo odun to n bọ.

No comments:

Post a Comment