Ewon odun meji ni adajo ju Ojogbon Akindele si o

Onidajo Maureen Onyetenu ti ju Ojogbon Richard Iyiola Akindele sewon odun meji gbako laifaaye faini sile fun un.

Akindele, oluko tele ni yunifasiti OAU ni won fesun kan pe o beere ibalopo eemarun lowo akekobinrin Monica Osagie lati fun un ni maaki.

Leyin iwadi nileewe OAU da a duro lenu ise, ti ajo ICPC naa tun gbe e lo sile ejo giga ijoba apapo to wa nilu Osogbo.

Esun merin otooto ni won fi kan Akindele, o si so pe oun jebi awon esun naa.

Idi niyii ti Onidajo Onyetenu fi so pe ki Akindele lo faso penpe roko oba fun odun meji lati le je eko fawon alagbere bii tire.

No comments:

Post a Comment