PDP ni ki Oyetola ma yọ ju, ijoba fidie lo n se

Egbe oselu PDP nipinle Osun ti so pe bii igba teeyan kan fi abala idi kan joko lori aga ni bi won se bura fun Alhaji Gboyega Oyetola lana an gege bii gomina ipinle Osun.


Ninu atejade kan ti alaga egbe naa l'Osun, Onorebu Soji Adagunodo fi sita lo ti ni ijoba fidie ni Oyetola ti egbe oselu APC bere nitori laipe rara ni ile ejo to n gbo esun to suyo ninu idibo naa yoo le e pada sile.

Adagunodo ni ko si eni ti ko mo kaakiri pe eru ati makaruuru lawon egbe oselu APC lo lati yi ife okan awon araalu po lasiko idibo ojo kejilelogun ati ojo ketadinlogbon osu kesan odun yii.

Alaga yii ni ẹri to ka-n-ka, ti ko se e foju fo da legbe PDP ti ko lo siwaju awon adajo ile ejo to n gbo esun naa, bee ni ko si le rorun fun awon adajo naa lati gbabode nitori gbogbo agbaye lo n wo wọn.

O waa ro Gomina Oyetola lati rora se, paapaa nipa eto inawo ipinle Osun nitori ohun ti ẹẹrun rẹ ba ṣe, o di dandan ki ojo Seneto Ademola Adeleke to je oludije egbe PDP ninu idibo naa bẹ ẹ wo ni kete ti ile ẹjọ ba ti da etọ rẹ pada fun un.

Bakan naa ni Adagunodo rọ awọn eeyan ipinle Osun lati mase kaare ninu adura ati ireti, pẹlu idaniloju pe, laipe ni imole yoo tan.

No comments:

Post a Comment