Ayọ ọkan awon oluko ati akekoo lawon ileewe ijoba kaakiri iha Ila-oorun Osun ko see fenuso lana an nigba ti Onorebu Ajibola Famurewa pin oniruuru awon nnkan ikekoo ati ikowe fun won.
Famurewa, eni to n soju awon eeyan Guusu Ijesa lowolowo nile igbimo asofin apapo labe egbe oselu APC lo tun n gbero lati lo soju awon eeyan agbegbe Ife/Ijesa nile igbimo asofin agba orileede yii lodun to n bọ.
Nibi eto naa, eleyii to waye ni papa isere Hope Middle School, Ilesa ni awon akekoo atawon oluko kaakiri awon ileewe ti duro wamuwamu ti won si n kan saara si Famurewa fun itura to mu ba eto ẹkọ lagbegbe naa.
Nigba to n ba awon oniroyin soro, Onorebu Famurewa ni kii se igba akooko niyen ti oun yoo ko ipa pataki lori idagbasoke eto eko lagbegbe yen nitori ohun kii rẹyin ninu ohunkohun to je mọ eto ẹkọ to ye kooro.
O ni ara n bẹ ninu ohun lati da fun igbayegbadun awon eeyan oun, ati pe ife naa ko nii dinku ti won ba le fun oun lanfaani lati soju won nile igbimo asofin agba orileede yii lodun 2019.
Lara awon eeyan jankanjankan ti won wa nibi eto nla naa ni alaga ajọ to n ri si eto eko kariaye nipinle Osun, Alhaji Fatai Kolawole, Onorebu Tunde Ayeni atawon miin.
Ninu oro tire, Alhaji Fatai Kolawole gbosuba fun Famurewa fun ife to ni si eto eko, o ni awon nnkan elo ikekoo naa yoo mu ki ikeko ro awon oluko lorun, bee ni yoo si mu ki ise tete ye awon akekoo fun igbega Ila-oorun Osun ati oruko rere ipinle Osun lapapo.
No comments:
Post a Comment