Awọn mọlẹbi ọmọdekunrin kan, Kazeem Yusuf ni wọn ti rawọ ẹbẹ si awọn ẹlẹyinju aanu nipinlẹ Ọṣun ati lorilẹede Naijiria lati jọwọ ṣiju aanu wo wọn nipa owo to to miliọọnu mejila naira ti wọn nilo funtọju aisan kidinrin to n yọ ọ lẹnu.
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ẹgbọn Yusuf, Uthman Kazeem ṣe sọ, ọdun bii mẹta sẹyin ni wọn ṣakiyesi pe ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn naa ni arun ifunpa giga, latigba naa si ni wọn ti n lo oniruuru oogun tawọn dokita n kọ fun un.
Ọdun meji sẹyin to dabi ẹni pe wahala naa pọ si ni wọn gbe Yusuf pada sileewosan, igba yẹn ni wọn sọ esi ibanujẹ naa fun wọn pe kidinrin ọmọkunrin to n kawe lọwọ nileewe University tilu Ilọrin nigba naa ti bajẹ.
Uthman ni orukọ ti wọn pe aisan ti Yusuf ni ọhun ni End stage renal disease (kidney failure), secondary to Hypertensive Nephrosclerosis. Latigba naa ni wọn si ti n sare sọtun sosi lati wa ojutu si nnkan to n ṣe e.
Gẹgẹ bii ẹni to jafafa nileewe, to si mọ ẹkọ nipa eto ọgbin to n kọ ni UNILORIN lamọdaju, Yusuf pari pẹlu maaki Second Class Upper, bẹẹ ni wọn si gbe e lọ sipinlẹ Ogun lati lọ sinru ilu.
Ṣugbọn ko ba a le ni amojuto to peye, ẹgbọn rẹ, Uthman ba a ṣeto isinru ilu rẹ titi ti wọn fi gbe e silu Abuja nibi tiyẹn n gbe, o si pari eto isinru ilu ọlọdun kan ọhun loṣu kẹwa to kọja yii.
Ṣe ni Yusuf lọ ba ọkan lara awọn ọrẹ re ṣere lo ku ọla ti yoo gbawe ẹri mo yege isinru ilu, bo ṣe ṣubu lulẹ ti ko le da dide mọ niyẹn, latigba naa lo si ti dero ileewosan Wuse General Hospital nilu Abuja.
Yatọ si awọn oogun kekeke ti wọn n ra fun Yusuf ọmọbibi ilu Ọbaagjn nijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ Ọṣun, ẹgbẹrun lọna igba naira ni owo mansinni(dialysis) to fi n ṣe ẹmi loṣooṣu
Lati le jẹ ki ọmọdekunrin yii wa lalaafia, Uthman ṣalaye pe Yusuf nilo kidinrin miin, awọn dokita si ti sọ pe yoo nilo to miliọọnu lọna mejila naira, bẹẹ ni ipa ti pin fun awọn mọlẹbi rẹ.
Idi niyẹn ti wọn fi n bẹ gbogbo awọn eeyn orilẹede yii lati ṣaanu Yusuf nipasẹ akanti nọmba awọn banki rẹ yii, ki oun naa le gbe aye bii awọn akẹẹgbẹ rẹ to ku.
Bank: GTB
Account No: 0121796788.
Or Bank: Access
Account No: 0763201557
Bẹẹ ni wọn le ba a sọrọ nipasẹ nọmba foonu yii: 0813 478 0908.
No comments:
Post a Comment