Ah! Eefin jẹneretọ lo pa Sajenti Mary atomo re meta sinu ile l'Osogbo

iroyin

Lowolowo bayii, ninu awon marun ti won sun sinu ile won lagboole Oloosaoko leyin mosalasi nla ilu Osogbo, awon merin ti ku.






Sajenti Mary to n sise lolu ileese olopa to wa nilu Osogbo, omo re meji ati omo-omo re kan ti jade laye.


Omo-omo re toun ko tii ju omo osu merin lọ lo wa lodo awon alabagbe obinrin olopa naa bayii.


A gbo pe eefin jenereto ti obinrin yii tan sinuu kisinni re lo seku pa won ki ile to mo.

No comments:

Post a Comment