Olopaa to ba gba owo lowo oloselu lasiko ibo yoo rugi oyin - Shogunle

iroyin/oselu

Ileese olopaa orileede yii ti kilo fun awon osise re ti won yoo kopa ninu idibo gomina ipinle Osun ti yoo waye lose to n bo lati sora gidigidi ninu iwa ati ise won nitori pe pampe ofin yoo mu eyikeyi to ba gbabode pelu awon oloselu lati se magomago ibo.


Igbakeji komisanna olopaa ti eka to n gbo aroye awon araalu, Public Complaint Rapid Response Unit, PCRRU, Ogbeni Abayomi Shogunle lo sekilo yii lasiko to sabewo sodo awon asojukoroyin l'Osogbo.

Shogunle ni awon wa nipinle Osun lati rii pe ko si olopaa kankan to huwa aito, saaju, lasiko ati leyin idibo gomina yii, yala pelu awon oloselu tabi si awon araalu.

O ni olopaa to ba gba owo abetele lowo awon oloselu lati huwa ti ko bofinmu lasiko ibo yoo rugi oyin nitori pe ileese olopaa ko nii fojuure wo iru eni bee.

Gege bo se wi, olopaa mewa ni won ti fowo osi juwe ile fun leyin ti won jebi iwadi ifisun awon araalu lẹnu odun meji ti won ti gbe PCRRU kale lorileede yii ati pe owo abetele to to milioonu mokanla naira lawon ti gba lowo awon olopaa alailojuti, ti awon si da won pada fun oninnkan.

O ni PCRRU wa nipinle Osun lati sepade pelu gbogbo awon ti oro idibo yii kan, ki won le mọ pe alaafia ni opakutele idibo ti ko ni magomago ninu.

Shogunle ni awon ti pari gbogbo eto bonkele lati fi mu olopaa to ba huwa aitọ lasiko ibo, bee naa ni ọwọ ofin yoo te eyikeyi oloselu to ba n pin owo kaakiri lojo naa.

No comments:

Post a Comment