Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Adesoji Aregbesola ti so pe gbagada ni ilekun egbe oselu APC si sile fun gbogbo awon ti won ti fi egbe naa sile lati pada, bee ni awon yoo gba won towotese ti won ba pinnu lati tun ero won pa.
O ni, ni ilẹ to mọ loni, ko si egbe oselu miran lara awon ti won n dupo gomina l'Osun ti oludije re kunju osunwon bii Alhaji Oyetola ti egbe oselu APC, yala pelu opolo pipe tabi imo iwe, idi si niyii ti isegun fi daju fun egbe naa.
Ojo isegun to koja ni gomina soro yii lasiko ti ọkọ ipolongo ibo oludije funpo gomina labe APC, Ogbeni Isiaka Adegboyega Oyetola atigbakeji rẹ, Benedict Olugboyega Alabi de ilu Ikire nijoba ibile Irewole.
Aregbesola ni o maa n ni saa ijoba to ba awon araalu lara mu, ko si si etan nibe teeyan ba so pe se ni Olorun mo on mo seto egbe APC fawon eeyan ipinle Osun pelu oniruuru ise idagbasoke to ti sele laarin odun mejo toun lo lori aleefa.
Aregbesola wa ro awon obitibiti ero ti won pejo nilu Ikire lati dibo won fun egbe oselu APC lojo kejilelogun osu kesan odun yii nitori pe oloootọ eeyan ati olopolo pipe to kosemose ni Oyetola toun fee gbejoba fun.
O ro won lati mase faaye gba awon 'eletan oloselu' lati fi buredi ko won lomi obe nipase aheso ti won le maa so kaakiri, ki won mo pe egbe to mona to si ye ki won tele ni egbe APC je.
Ninu oro ti oludije, Alhaji Oyetola dupe lowo awon eeyan agbegbe Ikire fun bi won se tu yaya jade pade ikọ ipolongo oun. O seleri fun won lati te siwaju ninu awon eto rere ti Aregbesola n se lori ipese ise fawon odo, igbelaruge ise agbe, amojuto eto ẹkọ, atunse oju ọna ati bee bee lo.
Egbon igbakeji gomina, Arabinrin Olubunmi Etteh naa ro awon eeyan ipinle Osun lati fi ibo won gbe Oyetola/Alabi wole, pelu ileri pe ayo ni yoo ja si gbeyin.
No comments:
Post a Comment