Enikeni to ba se owo osu awon osise ijoba basubasu l'Osun yoo kabamo - Adeleke
Oludije funpo gomina ipinle Osun labe asia egbe oselu PDP, Seneto Ademola Adeleke ti kilo fun gbogbo awon oloselu pelu awon kongila ti won n gbase nipinle Osun lati mase ni ipa ati ipin ninu nina owo to le ni bilioonu merindinlogun naira tijoba apapo fee funjoba Gomina Aregbesola basubasu.
Adeleke ni owo naa jẹ eyi to wa fun sisan owo osu tijoba je awon osise, sisan owo ifeyinti ati awon owo ajemonu to tọ si awon ti won ti fi agbara won wulo funjoba sugbon ti iwadi ti fidi re mule bayii pe ijoba ko setan lati lo owo naa fun nnkan to tọ si.
Adeleke ni ọkẹ aimoye bilioonu naira lo je pe ijoba apapo ti funpinle Osun lateyinwa lati fi yanju obitibiti gbese owo osu awon osise, sibe, iya nla lo n je awon osise ijoba pelu owo osu bii merinlelogbon tijoba je won.
O wa sekilo pe awon araalu ko nii laju won sile lasiko yii kijoba se owo eleyii basubasu. O ni gbogbo awon ti oro kan nipa owo naa gbodo kiyesara daadaa, ki won rii daju pe won fi gbogbo owo naa san owo osu ati ajemonu awon osise ijoba pelu awon osisefeyinti ni kiakia.
O fi kun oro re pe enikeni to ba gbiyanju lati na owo naa fun awon arumọjẹ kongila tabi le idibo lori yoo kabamo nitori gbogbo owo yii patapata nijoba oun yoo wadi ni kete ti oun ba ti de ori aleefa.
Bakan naa lo ni, leyin iwadi kikun, enikeni ti ajere iwa ibaje naa ba si le lori yoo foju winna ofin.
Adeleke wa tubo fi da awon eeyan ipinle Osun loju pe oun ko nii bojuweyin ninu ipinnu oun lati mu aye gbedemuke ni kete ti won ba ti le fi ibo won gbe oun wole lojo kejilelogun osu kesan odun yii.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment