Idunnu ati ayo lo ba de fun awon osise ijoba ipinle Osun ni bayii tijoba ti bere sisan ekunrere owo osu kejo fun won pelu awon ajẹsilẹ ẹtọ won.
Yato si pe won gba ekunrere owo osu kejo, ijoba san idaji-idaji ti owo won ti osu kesan, ikewa, ikokanla ati ikejila ti odun 2015 seku fun won gege bii adehun to wa laarin won.
Bee naa nijoba san owo awon osisefeyinti fun awon osu ọhun, gbogbo owo to to si awon osise fun isinmi won (leave bonus) fun odidi odun kan, iyen odun 2016 lo si di sisan pelu.
Komisanna feto isuna nipinle Osun, Bola Oyebamji lo salaye oro yii fawon oniroyin nilu Osogbo. O ni imuse ileri yii ko seyin bijoba ipinle Osun se ri owo to le ni bilioonu merindinlogun naira gba lara owo Paris Club latodo ijoba apapo.
O ni nigba ti Gomina Aregbesola ba awon ti oro awon osise ijoba kan soro lori owo naa, ijoba tun fi bilioonu meta kun owo naa, eleyii to so gbogbo re di bilioonu lona ogun o din meji naira lati le fi derin peeke awon osise.
Oyebamji salaye siwaju pe kii se igba akooko leyii tijoba yoo lo owo nla bee fun sisan owo osu ati ajemonu awon osise, nitori adehun awon ni pe ni kete ti eto oro aje ba ti gbenusoke lawon yoo bere sii san owo osu won lekunrere.
O ni dipo kijoba da awon osise duro, okan pataki lara awon asiwaju awon osise, to loruko rere, Alhaji Sunmonnu gba ijoba niyanju lati mu ona miin wo sisan owo osu. Ijoba bere sisan owo osu lekunrere fun awon ipele kinni si ikeje, idamarundinlogorin ninu ida ogorun fun awon ipele kejo si ikejila ati idaji fun awon ipele iketala soke.
O so siwaju pe odun 2014 ni eleyii bere titi di osu keje odun yii to dabi eni pe owo epo tun gbenusoke die si loja agbaye.
Oyebamji waa ro awon osise ijoba lati mase ya abaramoore jẹ, ki won te siwaju nipa sise atileyin funjoba Gomina Aregbesola.
No comments:
Post a Comment