Itara ti a fi gbe egbe APC wọle l'Ọsun naa la fi maa gbe ADP wọle ninu idibo yii - Dotun Babayemi

Dokita Dotun Babayemi ti so pe itara ati ipa ti awon ko jo lati fi satileyin fun Gomina Aregbesola to fi jawe olubori lodun 2014 naa lawon yoo lo lati fi gbe egbe oselu ADP wole lojo kejilelogun osu yii.

Babayemi, okan pataki lara awon omo egbe oselu ADP latiha Iwo-oorun Osun so pe opin ti de ba isejoba egbe APC l'Osun nitori gbogbo awon ti won se pataki ninu egbe ni won ti keyin si egbe naa bayii.

Lasiko ti meta ninu awon omo ile igbimo asofin ipinle Osun kẹru won kuro ninu egbe APC ti won si darapo mo egbe ADP lopin ose yii ni Babayemi so pe ijoraeniloju lo n koba awon asaaju egbe APC.

Awon asofin ti won kuro ninu egbe APC ọhun ni Onorebu Adebowale Akanbi lati Ede, Tajudeen Famuyide lati Iwo oorun Ilesa ati Abdullahi Ismail lati Iwo.

Ohun ti gbogbo awon asofin naa n so ni pe ko si adehun pe ara Eko ni Aregbesola yoo tun fa kale gege bii oludije funpo gomina leyin ti gbogbo awon gbaruku tii fun odidi odun mejo.

Won ni awon ko se ẹru awon ara Eko mọ, ijọba to bowo fun ero okan awon omo egbe lawon fee se, egbe to si le fun awon lanfaani tawon n fe ni egbe oselu ADP.


No comments:

Post a Comment