Pelu ibinu lawon odo agbegbe Orita Oloki nilu Ede nipinle Osun fi na omokunrin kan tinagije re n je Ẹja (fish) pa nirole ana latari pe o fi moto kolu awon akekoo marun, ti awon yen si ku loju ese.
Ipele to keyin ni eka awon ti won n kọle (building department) nileewe gbogbonise tijoba apapo to wa nilu Ede la gbo pe Eja wa, sugbon gbogbo awon akekoo ni won mo on gege bii omo yahoo-yahoo.
Ibi faaji la gbo pe oun atawon ore re ti n bo lojo naa, o si se konge asiko ti awon akekoo ti won sese n gbero lati darapo mo ileewe Poli Ede pari idanwo Post UTME won ni South Campus ileewe naa.
Ere asapajude ti Eja sa debi tawon omo naa ti n fẹsẹ rin lọ lo fa wahala naa, se lo n fi moto kolu won lo, ko si to di pe awon eeyan mo nnkan to n sele, marun ninu awon omo naa ti jade laye, awon yooku si farapa.
Bayii lawon odo ya bo Eja, wọn wọ ọ jade ninu mọto pẹlu ọti to n run lara rẹ, kia lawon ore re ti won jo wa ninu moto dawati, sugbon awon ọdọ dawọjọ lu Eja titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ
@@@@@@@@@@
No comments:
Post a Comment