Lati le se koriya fawon odo la se gbe eto ami-eye Osun Youths Ambassadors kalẹ - Alake Ajibola
Aare egbe kan to n ri si igbelaruge awon odo ti won ti lami laaka ninu ise ti won yan laayo, iyen Youths Reformers Initiatives, (YRI), Aminat Alake Ajibola ti so pe eto olodoodun won, Osun Youths Ambassadors Awards wa lati se iwuri fawon odo ni.
Lasiko to n soro nipa eto naa, eleeketa iru e, ti yoo waye loni ni Atlantis Civic Centre nilu Osogbo, Alakẹ ni awon odo mejilelogun ti won se fi yagan ni won yoo gba ami-eye nibe.
Lara awon odo ohun, awom metadinlogun ni won je omobibi ipinle Osun, nigba tawom marun to ku wa latawon ipinle miin.
O ni awon olopolo pipe ni won joko lati mu awon odo ti won yoo gba ami eye ohun leyin tawon araalu fi oruko aimoye odo sile fun ami-eye, laiwo ti esin, ilu, egbe oselu tabi eya ti won ti wa rara.
Nibi eto naa, eleyii ti yoo bere laago kan osan ni Oluwo ti ilu Iwoland, Oba AbdulRasheed Adewale Akanbi (TELU 1) ati Olowu Kuta, Oba AbdulHammed Adekunle Makama (Tegbosun 3) yoo ti jẹ ori-ade.
Dokita Dayo Sobowale (mNSE, R.Eng) ni oludanileko nibi eto naa, bakan naa si ni won n reti ogunlogo awon lookolooko lawujo, awon oloselu, awon olori agbegbe, awon olori esin, awon oniroyin ati bee bee lo.
Ajibola ni iwoye oun ni pe ti awon odo ti won n se takuntakun nidi ise ti won yan laayo ba n ri iwuri leekookan, eleyii yo mu won te siwaju, bee ni yoo si je eko fun awon odo to ku lawujo.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment