Iku doro! Baba Olusola Ajala ku lẹni ọgọrun ọdun

iroyin

Won ti kede ipapoda Venerable Emmanuel O. Ajala ti ilu Gbongan nijoba ibile Ayedaade nipinle Osun.


Baba yii, eni to dagbere faye lẹni ogorun odun lo bi gbajugbaja agbohunsafefe nni, Olusola Ajala.

Alufa ijọ Anglican Cathedral nilu Gbongan ni baba kọlọjọ too de, o si feyinti gege bii oga agba ileewe girama lopo odun seyin.

Leyin ti baba je ounje aaro tan lojo keta osu kesan odun yii ni baba fọwọ rọri ku ninu ile rẹ.

Won yoo kede eto isinku laipe.

1 comment: