Ope o! Saraki ti pari ija laarin Adeleke ati Ogunbiyi

iroyin/oselu

Aare ile igbimo asofin agba orileede yii, Seneto Bukola Saraki ti da alaafia pada si aarin Ademola Adeleke ati Dokita Akin Ogunbiyi.


Loni nipade alaafia naa waye nilu Abuja, nibe ni awon mejeeji si ti sepinnu lati sise papo nipinle Osun ki egbe PDP ba le rowomu ninu idibo to n bo.

A oo ranti pe oro idibo abele egbe naa to waye losu keje odun yii lo da wahala sile leyin ti won kede Ademola gege bii oludije to jawe olubori, ti Ogunbiyi si so pe eru wa ninu idibo naa.


No comments:

Post a Comment