Atundi ibo: Ile ejo pase pe kawon olopaa fi Alhaji Diekola atawon to ku latimọle sile

Ile ejo giga kan nilu Osogbo ti pase pe ki awon olopaa fi Alhaji Fatai Oyedele Diekola ti won ti ti mọle lati ojo Monde sile.



Gege bi adajo ile ejo naa, Onidajo A.O. Ayoola se so, aibowo fun etọ omoniyan ni bi won se ti Diekola atawon meji miin, Adekilekun Segun ati Sikiru Lawal mole lainidi.

Agbejoro Bukola Onifade lo gbe ileese olopa lo sile ejo. Adajo si pase pe ki won fi awon meteeta sile, ki won mase daamu won mo.

Ojo Monde lawon olopa so pe awon ba kaadi idibo alalope to to aadota lowo Diekola, latigba naa ni won ti ti won mole.

No comments:

Post a Comment