Awon sọja ya wọlu Osogbo nitori atundi ibo gomina

Inu iberubojo lawon eeyan ipinle Osun, paapa awon ara ilu Osogbo wa lati ale ana pelu bi ogunlogo awon sọja se n ya wonu ilu.


Ohun ti awon eeyan kọkọ ri ni pe awon olopa alaso dudu pelu awon olopa kogberegbe ti won sise aabo lasiko idibo gomina to waye lopin ose to koja n kuro ninu ilu laaro ojo Tusde si irole ojo naa.

Ko pe rara ni oniruuru moto awon soja n wole, titi di aaro yii ni won si n gba gbogbo ona wonu ilu Osogbo logun-logun, logbon-logbon.

Idi niyii tawon araalu fi n foya, ti won n ni o dabi eni pe awon ologun n mura wahala sile de atundi ibo ti yoo waye ni woodu meje ti ajo eleto idibo so pe idibo ko pari nibe.

A oo ranti pe lati ojo Monde ose yii lawon egbe oselu mejeeji ti won loruko ju ninu awon egbe oselu mejidinladota ti yoo kopa ninu eto idibo naa ti n fi esun toogi kiko ka kan araa won.

Awon ibi ti atundi ibo yoo ti waye ni Osogbo, Orolu, Ariwa Ife ati Gusu Ife.

No comments:

Post a Comment