Sallah 2018: Ẹ gbadura tako ohunkohun to le da iyapa silẹ lorileede yii - Aregbesola



Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti ro awon musulumi nipinle Osun lati lo asiko ayeye odun Ileya oni fun adura pataki lori isokan ati ibagbepo alaafia laarin gbogbo eya to wa lorileede Naijiria.


Ninu atejade 'e ku odun' ti oludamoran re lori oro iroyin, Sola Fasure fi sita ni Aregbesola ti fi imoriri re han si awon musulumi fun bi won se satileyin funsejo re lati odun mejo seyin to ti de ori aleefa l'Osun.

O ni eko idarijin omonikeji to wa ninu odun Ileya gbodo maa farahan ninu iwa ati ise awon musulumi nibi gbogbo ti won ba de, paapaa laarin awon elesin to ku, ki won si yago gedengbe si ohunkohun to ba le mu iyapa tabi ija eleyameya wa lorileede yii.

Aregbesola ro awon musulumi lati gba alaafia laaye lasiko idibo gomina ti yoo waye lojo kejilelogun osu kesan odun yii, o ni ki won mo pe Olorun nikan lo n gbe eeyan depo ati pe enikeni to ba fee fagidi debe kan fee se lasan ni.

O ni pelu bo ti se din ni osu meta bayii tisejoba oun yoo pari l'Osun, oun ko nii dawọ ise rere duro rara lati le se aseyori oniruuru ise toun ti dawole lati odun mejo seyin, ki ipinle Osun le wa loke tente nipa eto idagbasoke ati eto aabo laarin awon ipinle to ku lorileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment