Pelu idunnu lawon musulumi ti won je omo egbe oselu APC nijoba ibile Iwo-oorun Ilesa (Ilesa West) fi lo sile leyin ipade apapo egbe naa lopin ose to koja latari bi komisanna foro sayẹnsi ati imọ-ẹrọ nipinle Osun, Enjinia Remi Omowaiye se pin ounje odun ileya fun won.
Lara awon nnkan ti komisanna yii fun won ni isu tutu nlanla to je egbefa niye, opolopo agbo, maalu ati bee bee lo.
Nigba to n pin awon ebun ohun, Remi Omowaiye ni igbese naa ko seyin ona lati fi imoriri oun han fun atileyin awon eeyan oun ati lati le tubo mu ki inu won dun lasiko odun ileya yii.
O dupe lowo won fun bi won se duro ti isejoba Gomina Rauf Adesoji Aregbesola, bee lo tun ro won lati sa gbogbo ipa won lati le je ki Alhaji Gboyega Oyetola rowo mu ninu idibo gomina ti yoo waye lojo kejilelogun osu kesan odun yii.
Omowaiye fi da awon omo egbe APC loju pe kesekese ni gbogbo awon ise idagbasoke ti won ri lasiko Aregbesola, kasakasa n bo lona ti won ba le dibo fun itesiwaju ijoba rere nipase Oyetola nitori pe o je eni to ti ni oye pupo nipa isejoba labe isakoso Aregbesola.
Nigba ti okan lara awon asaaju egbe APC lagbegbe naa, Ogbeni Ademola Philip n dupe lowo komisanna fun ebun to fun won naa, o ni oloselu to lopolo pipe, to si maa n teti si imoran ni.
Ademola ni ounje to pin fawon naa je nnkan ti gbogbo omo egbe ti n reti nitori pe bo se maa n se ni gbogbo igba ti odun ba ti wa ni. O wa gbadura pe ki Olorun tubo maa pa a mo, ko si tubo maa pọ si ninu ohun rere.
No comments:
Post a Comment