Owo ti te Kunle, alarun opolo to ṣa ọba ilu Odo-Ọrọ Ekiti pa

Ilu Ado-Ekiti ni owo ti te Kunle, eni ti won so pe o larun opolo, to sa oba ilu Odo-Orọ nijoba ibile Ikole nipinle Ekiti, Oba Gbadebo Ogunsakin Olowoselu, pa laaro ana.

Inu ipade igbimo awon alase ilu naa la gbo pe Kabiesi wa laaro ana, ti Kunle fi kọkọ wọnu aafin, taarara lo si lo sori aga oba, o joko sibe ko too di pe awon ti won wa ninu aafin le e dide.

Bi Oba Olowoselu se setan to pada sinu aafin, la gbo pe Kunle, eni to je molebi kabiesi, fa obe yo, to si gun baba naa, eni to gun ori aleefa awon baba nla re lodu 1986, nigba ti won yoo si fi gbe e de osibitu, o ti waja.

Latigba yen ni won ti n wa Kunle kaakiri ko too di pe owo te e nilu Ado-Ekiti lale ana, o si ti wa lakolo awon olopaa to n wadi iwa odaran nibe.

No comments:

Post a Comment