Awon alase ileewe Obafemi Awolowo University, Ileefe ti pase pe kawon akekoo mefa ti owo te pe won je omo egbe okunkun lo rookun nile.
Inu osu keje odun yii la gbo pe awon omo egbe okunkun kan fagidi mu awon akekoo akeegbe won darapo, nigba ti asiri tu, awon eleto aabo bere sii dode won titi ti owo fi te awon akekoo mejila.
Won fa won le awon olopaa lowo, sugbon leyin iwadi lawon mefa jewo pe omo egbe okunkun lawon nitooto.
Idi niyii ti akowe yunifasiti naa, Arabinrin Magaret Omosule fi so ninu atejade kan pe awon alase ti fohun sokan pe kawon akekoo mefeefa ohun loo rookun nile titi abajade igbimo to n seto ibaniwi fawon akekoo.
Awon akekoo mefeefa naa niyii:
(1) ONYEKWUSI Praise Chinemerem, Matriculation number ASE / 2014/218
(2). OJO Abiodun Olamide, Matriculation number MCB /2012 /149
(3).UDE John, Matriculation number ASE /2015 /362
(4). OLADOYE Tobi Olakunmi, Matriculation number EGL /2014/ 383
(5) AYEYI Damilola Ayomide, Matriculation number EGL /2016 /075
(6) DAVIS Jesulayomi Olakunle, Matriculation number EGL / 2014 /207.
No comments:
Post a Comment