E mase gbagbe eko ifara ẹni jin ati igbọran ti odun Ileya kọ wa - Oyetola
Oludije funpo gomina ipinle Osun labe asia egbe oselu APC, Ogbeni Isiaka Adegboyega Oyetola ti ki awon musulumi ku oriire oju won to ri ayeye odun Ileya ti odun yii.
Gege bi oluranlowo re feto iroyin, Dayo Fasola se fi sita nilu Osogbo, Oyetola ro awon musulumi lati tubo fi ara won jin sinu ekọọ jijẹ olootọ, ifara ẹni jin, igboran, ati ifara ẹni rubọ ti odun naa ko won.
Oyetola ni o pon dandan ki awon musulumi ati kristiani tubo maa gbe po ni alaafia gege bo se wa latibere isejoba Ogbeni Rauf Aregbesola nitori ninu eyi nikan ni idagbasoke loniruuru ona yoo fi maa te siwaju nipinle Osun.
Bakan naa lo ro won lati gbaruku ti oun ninu erongba re lati te siwaju ninu ise Aregbesola gege bii gomina Osun ninu idibo osu kesan, pelu idaniloju pe gbogbo ileri ti oun ba se lasiko ipolongo ibo loun yoo mu se laiku eyokan.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment