Bi awon musulumi se n se ayeye ayajo odun Ileya loni, Seneto Babajide Omoworare ti ro won lati gbadura fun alaafia ati itesiwaju ipinle Osun ati orileede Naijiria.
Ninu oro ikini ku odun Ileya eleyii ti akowe iroyin re, Tunde Dairo fi sita ni Omoworare ti dawọ idunnu pẹlu awọn musulumi, o si ro wọn lati mase gbagbe eko igbagbo, igboran ati ifaraeni jin ti odun naa ko won.
Gege bo se wi, ojuse gbogbo ilu ni lati lo anfaani asiko odun Ileya fun wiwa oju Olorun ati gbigba ojurere re nipase gbigbadura fun awọn molebi, ipinle Osun, paapaa lasiko idibo yii ati orileede Naijiria lapapo.
Omoworare wa ro awon oludibo lati tubo nigbagbo ninu isejoba egbe oselu APC ti Aare Buhari n dari, bee ni ki won fi imoriri ise takuntakun ti Ogbeni Rauf Aregbesola ti se l'Osun han nipa didi ibo won fun Gboyega Oyetola gege bii gomina ati Olugboyega Alabi gege bii igbakeji re.
Seneto to n soju awon eeyan ekun Ila-Oorun Osun nile igbimo asofin agba naa salaye pe didi ibo fun itesiwaju ise rere Gomina Rauf Aregbesola nikan lo dara ju funpinle Osun lojo idibo, iyen ojo kejilelogun osu kesan odun yii.
No comments:
Post a Comment