Ibaṣepọ to dan mọran yoo wa laarin ilu Ede ati Osogbo ti mo ba di gomina - Adeleke

Seneto Ademola Adeleke ti seleri pe ko nii si gbonmi-sii-omi-o-to kankan mo laarin awon eeyan ilu Ede ati Osogbo ti oun ba ti di gomina ipinle Osun.


Lasiko abewo ti seneto to n dije funpo gomina labe egbe oselu PDP yii se si Ataoja ti ilu Osogbo, Oba Jimoh Olanipekun, Larooye 11, lo salaye pe gomina gbogbo eeyan loun, kii se gomina ti yoo tori oselu bu ola fun enikan ju enikeji lo, idi niyii ti oun yoo fi wa ona alaafia laarin gbogbo awon ilu ti ede aiyede ba wa

Ademola Adeleke dupe lowo Ataoja fun bo se tewo gba oun lalejo laise pe awon so fun un tele, bee lo si yin oba naa lawo fun oniruuru itesiwaju to ti ba ilu Osogbo lenu igba to de ori aga awon baba nla re.

O ni gbogbo awon araalu ni won mo idile Adeleke gege bii idile alaanu, ti kii si fe ki iya je enikeni, idi niyii yo ni oun fi pinnu lati gba awon eeyan lowo inilara egbe oselu APC.

Ninu oro re, Oba Olanipekun dupe lowo Adeleke atawon ikọ re fun abewo naa. O waa ro o lati mo pe idagbasoke ilu Osogbo se pataki fun enikeni to ba je gomina nitori ibe ni olu ilu ipinle Osun.iroyin/oselu

No comments:

Post a Comment