Alaga ajo to n ri si oro ijoba ibile nipinle Osun, Alagba Peter Adebayo Babalola ti so pe ko si ooto ninu aheso to n lo kaakiri pe oun ti darapo mo egbe oselu SDP.
Babalola, eni to je okan lara awon oludije funpo gomina ipinle Osun ninu egbe oselu APC ko too di pe won mu Alhaji Oyetola so pe digbi loun si wa ninu egbe oselu APC.
O ni gbogbo awon oludije latinu egbe oselu to ku ni won n wa sodo oun lati le je ki oun darapo mo won sugbon esi kansoso ti oun n fun gbogbo won ni pe oun ko le titori ohun kohun kuro ninu egbe APC.
Babalola fi kun oro re pe lara awon abewo naa ni ti Seneto Iyiola Omisore ti egbe oselu SDP ati pe ko se e se fun oun lati le oludije egbe oselu kankan to ba fe wa sodo oun pada niwon igba to je pe ipinle Osun kan naa lo so awon papo.
No comments:
Post a Comment