Okan lara awon arinurode ti won maa n so asotele nipa ohun ti yoo sele lorileede yii, Primate Elijah Babatunde Ayodele ti ijo INRI Spiritual and Evangelical Mission, Oke-Afa, Isolo nipinle Eko ti so pe isoro nla ni yoo je fun egbe oselu APC lati maa sejoba lo nipinle Osun.
Lasiko ifilole iwe re kan to pe ni "Ikilo fun orileede Naijiria" ninu eyi to ti so asotele nipa opolopo nnkan ti yoo sele laarin odun yii si odun to n bo lo ti so pe ayafi ti egbe naa ba tete wa ojutuu si wahala to n sele ninu re nikan lo fi le nisegun.
Primate Ayodele ni ti wahala, eleyii ti won foju ri, ati eyi ti won ko ka si, to n sele ninu egbe APC Osun lowolowo bayii ba ba won wo ojo idibo, se ni ki won juwo si Osun nitori pe egbe oselu miin ni yoo gbajoba lowo Aregbesola.
No comments:
Post a Comment