Pelu bi idibo gomina ipinle Osun se ku ojo merindinlaadota bayii, egbe oselu APC ti mu Benedict Olugboyega Alabi (BOA) gege bii igbakeji fun Alhaji Gboyega Oyetola.
Bakan naa ni egbe oselu ADP ti kede Ojogbon Deolu Durotoye gege bii igbakeji fun Alhaji Moshood Adeoti.
BOA lo wa tilu Ikire, oun si ni aburo Onorebu Bunmi Etteh, o si wa lara awon ti won fife han fun ipo gomina ipinle Osun ninu egbe APC ko too di pe Alhaji Oyetola wole lasiko idibo piramari egbe naa.
Durotoye lo je okan lara awon oludije ninu egbe PDP sugbon to juwọ sile fun Dokita Ogunbiyi. Leyin ti won kede Adeleke gege bii oludije o binu kuro ninu egbePDP.
No comments:
Post a Comment