Osun 2018: Onidajo Olamide Oloyede ni igbakeji gomina fegbe oselu ADC

Egbe oselu African Democratic Congress, ADC ti kede Adajofeyinti Folahanmi Olamide Oloyede gege bii igbakeji gomina fegbe naa ninu idibo to n bo yii.



Obinrin takuntakun naa ni yoo se igbakeji fun akowe funjoba ipinle Osun nigba kan ri, Alhaji Fatai Akinbade.

Omobibi ilu Ilesa ni, ija awon osise ijoba atawon osisefeyinti lo da wahala sile laarin onidajo yii atijoba ipinle Osun ti ajo to n ri si oro awon agbejoro lorileede yii fi ni ko feyinti ni tipatipa.

No comments:

Post a Comment