Oyetola di oludije funpo gomina ninu egbe APC; o nawọ ife sawon ti won fidi rẹmi


Olori osise loofisi gomina l'Osun, Alhaji Isiaka Gboyega Oyetola ni won ti kede gege bii oludije ti yoo soju egbe oselu APC ninu idibo gomina ti yoo waye nipinle Osun lojo kejilelogun osu kesan odun yii.



Bo tile je pe awon oludije kan lara awon metadinlogun to ye ki won jo kopa ninu idibo abele to waye lanan so pe awon ko kopa mo latari oniruuru magomago ti won so pe o waye ninu e, sibe, awon omo egbe oselu APC tu yaya jade nipinle Osun lati dibo.

Leyin ohun gbogbo, eyi ni esi idibo naa:


Ninu oro idupe re, Oyetola fi idunnu han si bi awon omo egbe se fi tayotayo dibo, ti oun si jawe olubori, o wa ro gbogbo awon oludije to ku lati fowo wonu, ki won si je kawon fi ife gbe egbe naa doke tente.

No comments:

Post a Comment